Jump to content

Movement Strategy/Events/Documentation/27 June/Summary/yo

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Movement Strategy/Events/Documentation/27 June/Summary and the translation is 98% complete.

Lílànà fún Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ Wikimedia

Àwọn àwòrán lát'orí ìpàdé náà.

Bíí àjọṣepọ̀ Wikimedia ti gbòòrò láti kári àwọn iṣẹ́-àkànṣe èdè tó ju òòdúnrún lọ, àti àwọn ẹ̀ka tó fẹ́ẹ̀ tó igba, síbẹ̀ kò sí àkọọ́lẹ̀ kankan tí ó pín ipa àti ojúṣe àwọn ará àti ẹ̀ka wọ̀nyíí. Àlàfo yìí ni àwọn ìmọ̀ràn lát'orí Strategy Àjọṣepọ̀ nwò láti dí pẹ̀lú Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀, ìwé-òfin tí yíò ràn wá lọ́wọ́ láti mọn "Ìlànà àpaapọ̀ fún ètò ṣíṣe ìpinnu". Ó tún jẹ́ àkòrí tí àwọn ọmọ ará Wikimedia tó lé lọ́gọ́rùn jọ wà papọ̀ láti jíròrò lóri ní 27 June, fún ìlépa ìpohùnpọ̀ ní ìjíròrò gbangba.

Ṣíṣẹ̀dá Ìwé-Àdéhùn Àjọṣepọ̀ nílò ẹgbẹ́ fún kíkọ, tó ní ìmọ̀ àti onírúurú ènìyàn. Ìbéèrè ni: Báwo ni à ṣele mú èyí ṣe? Àbá wáyé fún ètò pínpín àwọn ìjókò ìgbìmọ̀ náà ní ìdógba pẹ̀lú àwọn agbègbè mẹ́jọ̀ọ àgbáyé. Àbá tún wáyé fún pínpín ìjókò náà káàkiri ẹ̀ka Wikimedia: àwọn oníṣẹ́ ayélujára, ẹ̀ka tàbí Wikimedia Foundation. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé pínpín ìjókò náà ní ìdí agbègbè dára, àwọn olùkópa gbà wípé kìí ṣe gbogbo ìjókò ni ó yẹ kí á pín dọ́gba. A tún lè jẹ́ kí ó ṣeéṣe kí a fi kún iye ìjókò láti jẹ́ kí a lè ro àwọn ìdíjú àjọṣepọ̀ pọ̀ ní yíyan ẹgbẹ́ yìí.

Àpẹẹrẹ àwọn èsì lát'orí ìwé-ìwádìí tí a pín fún àwọn olùkópa
Abala àkọ́kọ́: Ní iye àwọn ìjọ́kọ̀ àìyípadà fún àwọn iṣẹ́-àkànṣe, ẹ̀ka Wikimedia, àti WMF
Abala àkọ́kọ́: Ní ìrètí fún ìmọ̀ye àti onírúurú láì sí àwọn ìjọ́kọ̀ àìyípadà fún àwọn iṣẹ́-àkànṣe, ẹ̀ka Wikimedia, àti WMF

Before the conversation, the Wikimedia Foundation shared a proposal for selecting members of the Charter’s drafting group. The proposal received several endorsements. There was also significant support for random selection, inspired by citizen assemblies, which may avoid bias and focus on representing the movement rather than individual communities. Regardless of the method, should there be a single selection process globally? A global selection process risks turning into a “popularity contest”, but it is difficult to decide on behalf of which “region” or “group” someone is nominated locally. Because this discussion has been going in loops for a while, there was a question about setting a deadline (tentatively, July 21st), after which a decision would be made by the Wikimedia Foundation regarding the selection process.

Kí àwọn ará Wikimedia tó lè farawọn sílẹ̀ láti darapọ̀ mọ́n ìgbìmọ̀ fún kíkọ ìwé-àdéhùn, wọ́n gbọdọ̀ mọ iye iṣẹ́ tí à nbèrè lọ́wọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ gbà wípé iye wákàtí tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yí ò jọ̀wọ́ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ yí ò jẹ́ bíi máàrún. Ìbéèrè tó wà nlẹ̀ ni, bóyá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí yẹ kí wọ́n ní òye èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè nínú ẹgbẹ́ lè jẹ́ ìpèníjà, síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará wikimedia ni kò ní òye èdè Gẹ̀ẹ́sì, tí ìjíròrò elédè kan yí ò yọkúrò. Àwọn àbá tí a ti mú wá ni: ẹ̀rọ ìtúmọ̀, ìtúmọ̀ ojú-ẹsẹ̀ ní àwọn ìpàdé, àti/tàbí Oríṣiríṣi ìgbìmọ̀ fún èdè kọ̀ọ̀kan.

Ìjíròrò orí ayélujára yí ò tẹ̀síwájú lẹ́hìn ìpàdé 27 June, àwọn olùsètò Strategy Àjọṣepọ̀ ngbìyànjú láti rí ìkoríta àwọn èrò ọ̀tọ̀. Fún ìdí èyí, a ti ṣe àtúnṣe sí àbá tí Wikimedia Foundation gbé kalẹ̀. Bí àwọn ìjíròrò ṣe ntẹ̀síwájú, tí a sì nrí àwọn ìpohùnpọ̀, àwọn olùṣètò Strategy Àjọṣepọ̀ yí ò tẹ̀síwájú láti ṣètò ìpè fún àwọn ará láti darapọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ fún kíkọ ìwé-àdéhùn. A lérò láti bẹ̀rẹ̀ ètò yí ní ìparí July pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwọn ará Wikimedia. Fún ìròyìn ọjọ́ iwájú, tẹ̀lé ìwé-ìròyìn fún Strategy Àjọṣepọ̀ tàbí ẹ̀ro Telegram wa.

Àwọn èsì ìwádìí

Lákòkò àwọn ìjókò mẹ́tàa ìpàdé yìí, a pín ìwé-ìwádìí méjì fún àwọn olùkópa: a pín ìwé-ìwádìí àkọ́kọ́ kí ìjíròrò tó bẹ̀rẹ̀, a sì pín ìkejì lẹ́hìn náà. Àwọn èsì tí a rí gbà ni a fi sí nú àwọ̀rán tó wà ní sàlẹ̀.

Ètò Ìṣẹ̀dá

Yíyàn/Ìdìbò

Ìfarajìn

Àwọn ìtọ́kasí