Jump to content

Àpéjọ Diversity Wikimedia 2017

From Meta, a Wikimedia project coordination wiki
This page is a translated version of the page Wikimedia Diversity Conference 2017 and the translation is 88% complete.
Outdated translations are marked like this.
Main Program Scholarships Ambassadors Volunteers Participants Venue and visa Travel guide Discussion Documentation



kíni ìdí fún Àpéjọ Diversity?

Iṣẹ́ Wikimedia ni láti fún gbogbo ènìyàn ní àyè ọ̀fẹ́ láti pín àwọn onírúurú ìmọ̀ àti láti jé kí onírúurú ènìyàn kópa láti jékí dídára rẹ̀ dúró mú sin-sin, fún gbígbòrò àwùjọ Wikimedia àti àwọn àjọṣepọ̀ wa. Pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà ìgbàgbọ́ wa, ìwúrí wa lórí akitiyan láti mú kí Wikipedia àti àwọn iṣẹ́ ìdáwọ́lé Wikimedia tókù jé kí onírúurú ènìyàn, àwùjọ, àgbétèlé àti ìmọ̀ kí ó kópa. A sì mọ̀ wípé iṣẹ́ pọ̀ fún wa láti ṣe.

Oríṣìiríṣìi èrò fún diversity lóti jásí àwọn ìgbésè nínú àwùjọ Wikimedia, nítorínà, (àìsí) diversity sì túnbọ̀ jẹ́ orísùn àwòkọ́ọṣe fún ọ̀pọ̀ nínú àwọn olùfarajìn Wikimedia láti gbé ìgbésè fún gbígbòrò iṣẹ́ ìmọ̀ ọ̀fẹ́.

Wikimedia Sverige (ti Sweden) ngbèrò kí àpéjọ yìí jẹ́ àyè alákoorí fún àwọn ará Wikimedia láti jíròrò àti láti pín òye ìjìnlẹ̀ àti ìrírí nínú àwọn ìpílẹ̀sẹ̀ wọ̀nyí. Kíni ati kọ́ nínú gbígbé ìgbésè àjùmọ̀ gbé ti ọ̀nà Wikimedia fún àwọn ìpílẹ̀sẹ̀ tí ó jákèjádò láti fikún diversity nínú àwọn iṣẹ́ ìdáwọ́lé Wikimedia? Báwòni ìmọ̀ (àjùmọ̀ ni) yìí lè túnbọ̀ darí àwọn ìgbésè?

A fẹ́ ṣẹ̀dá àpéjọ tí yíó pèsè pẹpẹ fún wa láti jìròrò lórí àwọn ìrírí nínú iṣẹ́ ní àyè diversity ti Wikimedia. A fẹ́ kí àwọn olùkópa lè pàdẹ́, kí wọ́n sì jìròrò àwọn orísìirísìi abala diversity, bìi ọ̀rọ̀ diversity akọ àti abo, ara àti ọpọlọ, èdè, ti jẹ́ọ́gráfì, àti ti ẹ̀yà. Lápàapọ̀, alè ṣàwárí àwọn ohun tí àwọn abala yìí ní tó papọ̀, ní ọ̀nà agbára, ìkópa àti ànfààní, àti bí òṣe jọmọ́ ojúlówó àti àkàyẹ ìmọ̀ ọ̀fẹ́. Ní ipa àwọn ìsopọ yìí, a ní ìrètí láti ṣẹ̀dá òye àjọmọ̀ lóri bí diversity ṣe n fi agbára fún ipa Wikimedia àti àwọn ọ̀nà láti jọṣepọ̀ àti gbígbòrò agbára láti ṣe àṣeyọrí lórí àwọn ìlépa ìgbìyànjú wa.

Inú wa dùn láti kéde wípé Katherine Maher, Elétò Àgbà láti Wikimedia Foundation, yíó wásí àpéjọ yìí.

Tani àpéjọ yìí wà fún?

Àn retí ní pàtó àwọn olùkópa láti ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ tí wọn kò ní ìfihàn tó pójú òṣùwọ̀n ní Wikimedia, àwọn olùkópa láti ọ̀dọ̀ àwọn àwùjọ ìpín kékeré, àti àwọn olórí diversity ní Wikimedia àti àwọn àgbájọ tí iṣẹ́ wọn pàpọ̀.

Ìgbìmọ̀ Ètò

Ṣíṣe ìpinnu lóri ètò fún àpéjọ yìí dá lóri ìrírí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ yìí. Ìgbìmọ̀ Ètò tẹ́wọ́ gba àwọn àbá àti àgbéwọlé, tí ẹni kẹ lè fẹ́ fisílẹ́ ní orí ojúewé ọ̀rọ̀.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́

Ìforúkọ̀sìlẹ̀

Ìforúkọ̀sìlẹ̀ fún Àpéjọ Diversity Wikimedia 2017 ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ báyìí.

(All questions can be found here)

Kíni ìdí láti forúkọ̀sìlẹ̀?

  • Kíkópa: Gbogbo àwọn olùkópa tí ó níìfẹ́ gbodọ̀ fi orúkọ̀sìlẹ̀ láti fi ìníìfẹ́sí wọn sí wíwá àpéjọ yìí hàn, àti láti ríi pé ó tọ́ sí wọn ní torí àkóri àpéjọ náà.
  • Kópa nínù ètò: Abala àkọ́kọ́ nínú ìforúkọ̀sìlẹ̀ wà nípa ètò àpéjọ yìí àti àwọn ìbéèrè fún àwọn olùkópa tí ó níìfẹ́, láti jẹ́ kí ìgbìmọ̀ ìsètò mọ̀n ohun tí wọ́n fẹ́ kọ́, pín àti irú ìrírí tí wọ́n ní ipa iṣẹ́ wọn ní ẹ̀ka diversity Wikimedia. Àwọn olùkópa yìí ni kókó àpéjọ yìí.
  • Darí àwọn ìṣe: Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi orúkọ̀sìlẹ̀ léè sọ tí wọ́n bá fẹ́ darí àwọn ìṣe ní àpéjọ yìí bìi ọ̀rọ̀, ìjíròrò, àti/tàbí iṣẹ́ kíkọ́. Pẹ̀lú àlàyé yìí, ìgbìmọ̀ ìsètò yíó kàn sí àwọn olùkópa lóri ọ̀nà tí wón lè dásí àpéjọ yìí àti kíkópa nínù ètò.
  • Forúkọ̀sìlẹ̀ fún owó ìrànlọ́wọ́: Fọ́ọ̀mù ìforúkọ̀sìlẹ̀ tún ní abala fún ìforúkọ̀sìlẹ̀ fún owó ìrànlọ́wọ́ tí àwọn olùkópa tí wọ́n fẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti lè wá sí àpéjọ yìí, lè fi orúkọ̀ sì. Irú àwọn ẹni báyìí gbudọ̀ fi orúkọ̀sìlẹ̀ kí a tó wọ̀ 20 August.

Olùbásọ̀rọ̀

ẹmá gbàgbé láti kàn sí wa

Wikimedia Diversity Conference

Àlàyé

Schedule

Ìṣètò

Hashtag

Hashtag:#DivCon17


Livrustkammaren is sponsoring a venue at the Royal Palace for the social activity on Friday.
The Swedish Post and Telecom Authority is funding our work with Wikispeech.