Universal Code of Conduct/Enforcement guidelines/Voting/Report/Announcement
Àkópọ̀ àwọn ìdásí lát'orí ìdìbò fún àwọn Ìlànà Ìgbófìnró Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC)
Ẹ n lẹ́ níbẹ̀ yẹn oo,
Ẹgbẹ́ olùṣètò fún Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí (UCoC) ti parí ìtú sí wẹ́wẹ́ àwọn èsì tó tẹ̀lẹ́ ìbò lórí àwọn ìlànà Ìgbófìnró Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí.
Lẹ́hìn ìparí kíkọ ọ̀rọ̀ inú àwọn ìlànà Ìgbófìnró UCoC ní 2022, àwọn ará àjọṣepọ̀ Wikimedia dìbò lórí àwọn ìlànà Ìgbófìnró wọ̀nyíí. Ìbò wáyé lát'orí iṣẹ́-àkànṣe 137, lára àwọn mẹ́sàn tó mókè ni: àwọn Wikipedia Gẹ̀ẹ́sì, German, Faransé, Russia, Polish, Spanish, Chinese, Japanese, Italian, àti Meta-wiki.
Àwọn tó dìbò ní ànfààní láti pèsè àwọn ìdásí lórí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé-ìlànà náà. Àwọn olùkópa 658 ni ó fi ìdásí kalẹ̀. 77% àwọn ìdásí ni a kọ ní ède Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn olùdìbò fi ìdásí kalẹ̀ ní èdè 24, lará àwọn tó mókè ni Gẹ̀ẹ́sì (508), German (34), Japanese (28), Faranse (25), àti Russia (12).
A fi ìjábọ̀ ránṣẹ́ sí Ìgbìmọ̀ fún Àtúnṣe Kíkọ, tí yíò ṣe àtúnṣe sí Àwọn ìlànà Ìgbófìnró ní ìbámu pẹ̀lú èsì àwọn ará Wikimedia tí ó wá lát'orí ìdìbò tí ó ṣẹ̀ ṣẹ̀ parí. Ìjábọ̀ ti gbangban yìí wà lórí Meta-wiki níbí. Àwọn ìtúnmọ̀ wà fún ìjábọ̀ yìí lórí Meta-wiki. Please help translate to your language
Lẹ́ẹ̀kan si, a dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀yin tó kópa nínú ìdìbò àti àwọn ìjíròrò. À npe gbogbo ènìyàn láti kópa nínú àwọn ìjóròrò ará tó nbọ̀ lọ́nà. Ẹ lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí lóri Meta-wiki.
Ní orúkọ ẹgbẹ́ olùṣètò Àlàkalẹ̀ Gbogboògbò fún Ìhùwàsí